Pular para o conteúdo
Publicidade

Filipi 2:3-8

3 2.3-4: Ro 12.10; 15.1-2.Ẹ má ṣe ohunkóhun nínú ìlépa ara tàbí ògo asán, ṣùgbọ́n ní ìrẹ̀lẹ̀ ọkàn kí olúkúlùkù ro àwọn ẹlòmíràn sí ẹni ti ó sàn ju òun lọ. 4 Kí olúkúlùkù yín má ṣe ro ohun ti ara rẹ̀ nìkan, ṣùgbọ́n ti ẹlòmíràn pẹ̀lú.

5 2.5-8: Mt 11.29; 20.28; Jh 1.1; 2Kọ 8.9; Hb 5.8. Nínú ìbáṣepọ̀ yin pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn, ẹ ni irú ìlépa ọkàn náà bí ti Kristi Jesu.

6 Ẹni tí, bí o tilẹ̀ jẹ́ ìrísí Ọlọ́run,

kò kà á sí ohun tí ìbá fi ìwọra gbámú láti bá Ọlọ́run dọ́gba.

7 Ṣùgbọ́n ó bọ́ ògo rẹ̀ sílẹ̀,

ó sì mú àwọ̀ ìránṣẹ́,

a sì ṣe é ni àwòrán ènìyàn.

8 Ó sì wà ní àwòrán ènìyàn,

ó rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀,

o sì tẹríba títí de ojú ikú,

àní ikú lórí àgbélébùú.

Estes versículos te tocaram? Ore agora!

+581 estão orando agora.

Junte-se à corrente de oração.

Filipenses
Ver todos os capítulos de Filipenses