37 18.37: Jh 3.32; 8.14,47; 1Jh 4.6. Nítorí náà, Pilatu wí fún un pé, "Ọba ni ọ́ nígbà náà?"
Jesu dáhùn wí pé, "Ìwọ wí pé, ọba ni èmi jẹ́. Nítorí èyí ni a ṣe bí mí, àti nítorí ìdí èyí ni mo sì ṣe wá sí ayé kí n lè jẹ́rìí sí òtítọ́, olúkúlùkù ẹni tí í ṣe ti òtítọ́ ń gbọ́ ohùn mi."
38 18.38-40: Mt 27.15-26; Mk 15.6-15; Lk 23.18-19; Ap 3.14. Pilatu wí fún un pé, "Kín ni òtítọ́?" Nígbà tí ó sì ti wí èyí tan, ó tún jáde tọ àwọn Júù lọ, ó sì wí fún wọn pé, "Èmi kò rí ẹ̀ṣẹ̀ kan lọ́wọ́ rẹ̀.