17 19.17-24: Mt 27.33-44; Mk 15.22-32; Lk 23.33-43.Nítorí náà, wọ́n mú Jesu, ó sì jáde lọ, ó ru àgbélébùú fúnra rẹ̀ sí ibi tí à ń pè ní ibi agbárí, ní èdè Heberu tí à ń pè ní Gọlgọta. 18 Níbi tí wọ́n gbé kàn án mọ́ àgbélébùú, àti àwọn méjì mìíràn pẹ̀lú rẹ̀, níhà ìhín àti níhà kejì, Jesu sì wà láàrín.
19 Pilatu sì kọ ìwé kan pẹ̀lú, ó sì fi lé e lórí àgbélébùú náà. Ohun tí a sì kọ ni,
Jesu ti Nasareti Ọba àwọn Júù.
23 Nígbà náà ni àwọn ọmọ-ogun, nígbà tí wọ́n kan Jesu mọ́ àgbélébùú tán, wọ́n mú aṣọ rẹ̀, wọ́n sì pín wọn sí ipa mẹ́rin, apá kan fún ọmọ-ogun kọ̀ọ̀kan, àti ẹ̀wù àwọ̀tẹ́lẹ̀ rẹ̀, ṣùgbọ́n ẹ̀wù àwọ̀tẹ́lẹ̀ náà kò ní ojúràn-án, wọ́n hun ún láti òkè títí jálẹ̀.
24 19.24: Ek 28.32; Sm 22.18. Nítorí náà wọ́n wí fún ara wọn pé, "Ẹ má jẹ́ kí a fà á ya, ṣùgbọ́n kí a ṣẹ́ gègé nítorí rẹ̀."
Ti ẹni tí yóò jẹ́: kí ìwé mímọ́ kí ó le ṣẹ, tí ó wí pé,
"Wọ́n pín aṣọ mi láàrín ara wọn,
wọ́n sì ṣẹ́ gègé fún aṣọ ìlekè mi."
Nǹkan wọ̀nyí ni àwọn ọmọ-ogun ṣe.
25 19.25: Mt 27.55-56; Mk 15.40-41; Lk 23.49; Jh 2.3; Mk 3.31; Lk 24.18; Jh 20.1,18. Ìyá Jesu àti arábìnrin ìyá rẹ̀ Maria aya Kilopa, àti Maria Magdalene sì dúró níbi àgbélébùú, 26 19.26: Jh 13.23; 20.2; 21.20.nígbà tí Jesu rí ìyá rẹ̀ àti ọmọ-ẹ̀yìn náà dúró, ẹni tí Jesu fẹ́ràn, ó wí fún ìyá rẹ̀ pé, "Obìnrin, wo ọmọ rẹ!" 27 Lẹ́yìn náà ni ó sì wí fún ọmọ-ẹ̀yìn náà pé, "Wo ìyá rẹ!" Láti wákàtí náà lọ ni ọmọ-ẹ̀yìn náà sì ti mú un lọ sí ilé ara rẹ̀.
Ikú Jesu
28 19.28-30: Sm 69.21; Mt 27.45-50; Mk 15.33-37; Lk 23.44-46; Jh 17.4. Lẹ́yìn èyí, bí Jesu ti mọ̀ pé, a ti parí ohun gbogbo tán, kí ìwé mímọ́ bà á lè ṣẹ, ó wí pé, "Òrùngbẹ ń gbẹ mí." 29 Ohun èlò kan tí ó kún fún ọtí kíkan wà níbẹ̀, wọ́n tẹ kànìnkànìn tí ó kún fún ọtí kíkan bọ inú rẹ̀, wọ́n sì fi lé orí igi hísópù, wọ́n sì nà án sí i lẹ́nu. 30 Nígbà tí Jesu sì ti gba ọtí kíkan náà, ó wí pé, "Ó parí!" Ó sì tẹ orí rẹ̀ ba, ó jọ̀wọ́ ẹ̀mí rẹ̀.