Pular para o conteúdo
Publicidade

Johanu 8:31-36

Àwọn ọmọ Abrahamu

31 8.31: Jh 15.7; 2Jh 9. Nítorí náà Jesu wí fún àwọn Júù tí ó gbà á gbọ́, pé, "Bí ẹ bá tẹ̀síwájú nínú ọ̀rọ̀ mi ẹ ó jẹ́ ọmọ-ẹ̀yìn mi nítòótọ́. 32 8.32: 2Kọ 3.17; Ga 5.1.Ẹ ó sì mọ òtítọ́, òtítọ́ yóò sì sọ yín di òmìnira."

33 8.33: Mt 3.9; Ga 3.7. Wọ́n dá a lóhùn pé, "Irú-ọmọ Abrahamu ni àwa jẹ́, àwa kò sì ṣe ẹrú fún ẹnikẹ́ni rí láé; ìwọ ha ṣe wí pé, ‘Ẹ ó di òmìnira’?"

34 8.34: Ro 6.16; 2Pt 2.19. Jesu dá wọn lóhùn pé, "Lóòótọ́, lóòótọ́ ni mo wí fún yín, ẹnikẹ́ni tí ó bá ń dẹ́ṣẹ̀, ẹrú ẹ̀ṣẹ̀ ni. 35 8.35: Gẹ 21.10; Ga 4.30.Ẹrú kì í sì í gbé ilé títí láé, ọmọ ní ń gbé ilé títí láé. 36 Nítorí náà, bí Ọmọ bá sọ yín di òmìnira ẹ ó di òmìnira nítòótọ́.

Estes versículos te tocaram? Ore agora!

+581 estão orando agora.

Junte-se à corrente de oração.