33 8.33: Mt 3.9; Ga 3.7. Wọ́n dá a lóhùn pé, "Irú-ọmọ Abrahamu ni àwa jẹ́, àwa kò sì ṣe ẹrú fún ẹnikẹ́ni rí láé; ìwọ ha ṣe wí pé, ‘Ẹ ó di òmìnira’?"
34 8.34: Ro 6.16; 2Pt 2.19. Jesu dá wọn lóhùn pé, "Lóòótọ́, lóòótọ́ ni mo wí fún yín, ẹnikẹ́ni tí ó bá ń dẹ́ṣẹ̀, ẹrú ẹ̀ṣẹ̀ ni. 35 8.35: Gẹ 21.10; Ga 4.30.Ẹrú kì í sì í gbé ilé títí láé, ọmọ ní ń gbé ilé títí láé. 36 Nítorí náà, bí Ọmọ bá sọ yín di òmìnira ẹ ó di òmìnira nítòótọ́.