6 7.6-7: Isa 29.13. Jesu dá wọn lóhùn wí pé, "Ẹyin àgàbàgebè yìí, òtítọ́ ni wòlíì Isaiah ń sọtẹ́lẹ̀ nípa tí ẹ̀yin àgàbàgebè, bí a ti kọ ọ́ pé:
" ‘Àwọn ènìyàn wọ̀nyí fi ẹnu wọn bu ọlá fún mi
ṣùgbọ́n ọkàn wọn jìnà sí mi.
7 Ìsìn wọn jẹ́ lásán,
ìkọ́ni wọ́n jẹ́ kìkìdá òfin tí àwọn ènìyàn fi ń kọ́ni.’
8 Nítorí tí ẹ̀yin fi òfin Ọlọ́run sí apá kan, ẹ̀yin ń tẹ̀lé àṣà àwọn ènìyàn."