17 Ọkùnrin kan láàrín ọ̀pọ̀ ènìyàn dáhùn pé, "Olùkọ́, èmi ni mo mú ọmọ yìí wá fún ọ láti wò ó sàn. Kò lè sọ̀rọ̀ rárá, nítorí tí ó ní ẹ̀mí àìmọ́.
22 Nígbàkígbà ni ó sì máa ń gbé e sínú iná àti sínú omi, láti pa á run, ṣùgbọ́n bí ìwọ bá lè ṣe ohunkóhun, ṣàánú fún wa, kí o sì ràn wá lọ́wọ́.
23 9.23: Mt 17.20; Lk 17.6; Mk 11.22-24. "Jesu sì wí fún un pé, ‘Bí ìwọ bá le gbàgbọ́: ohun gbogbo ni ó ṣe é ṣe fún ẹni tí ó bá gbàgbọ́.’ "
24 Lójúkan náà baba ọmọ náà kígbe ní ohùn rara, ó sì wí pé, "Olúwa, mo gbàgbọ́, ran àìgbàgbọ́ mi lọ́wọ́."