Ẹni tí ó tóbi jù ní ìjọba Ọ̀run
1 18.1-5: Mk 9.33-37; Lk 9.46-48. Ní àkókò náà ni àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu tọ̀ ọ́ wá, wọ́n bi í léèrè pé, "Ta ni ẹni ti ó pọ̀jù ní ìjọba ọ̀run?"
2 Jesu sì pe ọmọ kékeré kan sí ọ̀dọ̀ ara rẹ̀. Ó sì mú un dúró láàrín wọn. 3 18.3: Mk 10.15; Lk 18.17; 1Pt 2.2.Ó wí pé, "Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, àfi bí ẹ̀yin bá yí padà kí ẹ sì dàbí àwọn ọmọdé, ẹ̀yin kì yóò lè wọ ìjọba ọ̀run. 4 Nítorí náà, ẹni tí ó bá rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọmọdé yìí, ni yóò pọ̀ jùlọ ní ìjọba ọ̀run. 5 18.5: Mt 10.40; Lk 10.16; Jh 13.20.Àti pé, ẹnikẹ́ni tí ó bá gba ọmọ kékeré bí èyí nítorí orúkọ mi, gbà mí.
Òwe àgùntàn tó sọnù
10 18.10: Ap 12.11. "Ẹ rí i pé ẹ kò fi ojú tẹ́ńbẹ́lú ọ̀kan nínú àwọn kéékèèké wọ̀nyí. Lóòótọ́ ni mo wí fún yin pé, nígbà gbogbo ni ọ̀run ni àwọn angẹli ń wo ojú Baba mi tí ń bẹ ní ọ̀run. 18.10 Àwọn àkọsílẹ̀ àtijọ́ kan se àfikún ọ̀rọ̀ yìí ọ̀run. 11 Nítorí náà, Ọmọ Ènìyàn wá láti gba àwọn tí ó nù là .