Pular para o conteúdo
Publicidade

Romu 12:17-21

17 12.17: Òw 20.22; 2Kọ 8.21; 1Tẹ 5.15. Ẹ má ṣe fi búburú san búburú fún ẹnikẹ́ni. Ẹ má pèsè ohun tí ó tọ́ níwájú gbogbo ènìyàn. 18 12.18: Mk 9.50; Ro 14.19.Bí ó bá sé é ṣe, bí ó ti wà ní ipa tiyín, ẹ má wà ní àlàáfíà pẹ̀lú gbogbo ènìyàn. 19 12.19: Le 19.18; De 32.35; Hb 10.30.Olùfẹ́ mi ọ̀wọ́n, ẹ má ṣe gbẹ̀san ara yín, ṣùgbọ́n ẹ fi ààyè sílẹ̀ fún ìbínú Ọlọ́run; nítorí a ti kọ ọ́ pé, Olúwa wí pé, "Tèmi ni ẹ̀san, èmi ó gbẹ̀san." 20 12.20: Òw 25.21-22; Mt 5.44; Lk 6.27.Ní òdìkejì ẹ̀wẹ̀,

"Bí ebi bá ń pa ọ̀tá rẹ, fún un ní oúnjẹ;

bí òùngbẹ bá ń gbẹ ẹ́, fún un ní omi mu.

Ní ṣíṣe èyí, ìwọ ó kó ẹ̀yín iná lé e ní orí."

21 Má ṣe jẹ́ kí búburú ṣẹ́gun rẹ, ṣùgbọ́n fi rere ṣẹ́gun búburú.

Estes versículos te tocaram? Ore agora!

+581 estão orando agora.

Junte-se à corrente de oração.