3 Ṣùgbọ́n nínú ẹbọ wọ̀nyí ni a ń ṣe ìrántí ẹ̀ṣẹ̀ lọ́dọọdún. 4 Nítorí ko ṣe é ṣe fún ẹ̀jẹ̀ akọ màlúù àti ti ewúrẹ́ láti mú ẹ̀ṣẹ̀ kúrò.
5 10.5-9: Sm 40.6-8. Nítorí náà nígbà tí Kristi wá sí ayé, ó wí pé,
"Ìwọ kò fẹ́ ẹbọ àti ọrẹ,
ṣùgbọ́n ara ni ìwọ ti pèsè fún mi,
6 ẹbọ sísun àti ẹbọ fún ẹ̀ṣẹ̀ ni
ìwọ kò ní inú dídùn sí.
7 Nígbà náà ni mo wí pé, ‘Kíyèsi i (nínú ìwé kíká ni a gbé kọ ọ́ nípa ti èmi)
mo dé láti ṣe ìfẹ́ rẹ, Ọlọ́run.’ "
8 Nígbà tí o wí ni ìṣáájú pé, "Ìwọ kò fẹ́ ẹbọ àti ọrẹ àti ẹbọ sísun, àti ẹbọ fún ẹ̀ṣẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò ni inú dídùn si wọn" (àwọn èyí tí a ń rú gẹ́gẹ́ bí òfin). 9 Nígbà náà ni ó wí pé, "Kíyèsi i, mo de láti ṣe ìfẹ́ rẹ Ọlọ́run." Ó mú ti ìṣáájú kúrò, kí a lè fi ìdí èkejì múlẹ̀. 10 Nípa ìfẹ́ náà ni a ti sọ wá di mímọ́ nípa ẹbọ ti Jesu Kristi fi ara rẹ̀ rú lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo.