Pular para o conteúdo
Publicidade

Luku 4:16-21

16 4.16-30: Mt 13.53-58; Mk 6.1-6; Isa 13.14-16. Ó sì wá sí Nasareti, níbi tí a gbé ti tọ́ ọ dàgbà: bí ìṣe rẹ̀ ti rí, ó sì wọ inú Sinagọgu lọ ní ọjọ́ ìsinmi, ó sì dìde láti kàwé. 17 A sì fi ìwé wòlíì Isaiah fún un. Nígbà tí ó sì ṣí ìwé náà, ó rí ibi tí a gbé kọ ọ́ pé:

18 "Ẹ̀mí Olúwa ń bẹ lára mi,

nítorí tí ó fi àmì òróró yàn mí

láti wàásù ìyìnrere fún àwọn òtòṣì.

Ó ti rán mi wá láti wàásù ìdásílẹ̀ fún àwọn ìgbèkùn, àti

ìmúnríran fún àwọn afọ́jú,

àti láti jọ̀wọ́ àwọn tí a pa lára lọ́wọ́,

19 láti kéde ọdún ojúrere Olúwa."

20 Ó sì pa ìwé náà dé, ó fi í fún ìránṣẹ́, ó sì jókòó. Gbogbo àwọn tí ó ń bẹ nínú Sinagọgu sì tẹjúmọ́ ọn. 21 Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í wí fún wọn pé, "Lónìí ìwé mímọ́ yìí ṣẹ ní etí yín."

Estes versículos te tocaram? Ore agora!

+581 estão orando agora.

Junte-se à corrente de oração.