Àwọn aposteli méjìlá
12 6.12-16: Mk 3.13-19; Mt 10.2-4; Ap 1.13. 6.12: Lk 3.21; 5.16; 9.18,28; 11.1. Ni ọ̀kan nínú àwọn ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì, Jesu lọ sí orí òkè láti gbàdúrà, ó sì fi gbogbo òru náà gbàdúrà sí Ọlọ́run. 13 Nígbà tí ilẹ̀ sì mọ́, ó pe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀; nínú wọn ni ó sì yan méjìlá, tí ó sì sọ ní aposteli: