5 2.5-8: Mt 11.29; 20.28; Jh 1.1; 2Kọ 8.9; Hb 5.8. Nínú ìbáṣepọ̀ yin pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn, ẹ ni irú ìlépa ọkàn náà bí ti Kristi Jesu.
6 Ẹni tí, bí o tilẹ̀ jẹ́ ìrísí Ọlọ́run,
kò kà á sí ohun tí ìbá fi ìwọra gbámú láti bá Ọlọ́run dọ́gba.
7 Ṣùgbọ́n ó bọ́ ògo rẹ̀ sílẹ̀,
ó sì mú àwọ̀ ìránṣẹ́,
a sì ṣe é ni àwòrán ènìyàn.
8 Ó sì wà ní àwòrán ènìyàn,
ó rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀,
o sì tẹríba títí de ojú ikú,
àní ikú lórí àgbélébùú.