Pular para o conteúdo
Publicidade

Mika 4

Òkè Olúwa

1 4.1-3: Isa 2.2-4. Ní ọjọ́ ìkẹyìn

a ó fi òkè ilé Olúwa lélẹ̀ lórí àwọn òkè ńlá,

a ó sì gbé e ga ju àwọn òkè kéékèèké lọ,

àwọn ènìyàn yóò sì máa wọ̀ sínú rẹ̀.

2 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè yóò wá,

wọn yóò sì wí pé, "Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí á gòkè ńlá Olúwa,

àti sí ilé Ọlọ́run Jakọbu.

Òun yóò sì kọ́ wa ní ọ̀nà rẹ̀,

kí àwa kí ó lè rìn ní ọ̀nà rẹ̀."

Òfin yóò jáde láti Sioni wá,

àti ọ̀rọ̀ Olúwa láti Jerusalẹmu.

3 Òun yóò sì ṣe ìdájọ́ láàrín ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn,

yóò sì parí aáwọ̀ fún orílẹ̀-èdè alágbára jíjìn réré.

Wọn yóò sì fi idà wọn rọ ohun èlò ìtulẹ̀

àti ọ̀kọ̀ wọn di dòjé

orílẹ̀-èdè kì yóò gbé idà sókè sí orílẹ̀-èdè mọ́,

bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò kọ́ ogun jíjà mọ́.

4 4.4: Sk 3.10. Ṣùgbọ́n olúkúlùkù yóò jókòó lábẹ́ àjàrà rẹ̀

àti lábẹ́ igi ọ̀pọ̀tọ́ rẹ̀,

ẹnìkan kì yóò sì dẹ́rùbà wọ́n,

nítorí Olúwa àwọn ọmọ-ogun ti sọ̀rọ̀.

5 Gbogbo àwọn ènìyàn ń rìn,

olúkúlùkù ni orúkọ ọlọ́run tirẹ̀,

ṣùgbọ́n àwa yóò máa rìn ní orúkọ Olúwa.

Ọlọ́run wa láé àti láéláé.

Èrò Olúwa

6 "Ní ọjọ́ náà," ni Olúwa wí,

"Èmi yóò kó àwọn arọ jọ;

èmi yóò sì ṣà àwọn tí a lé kúrò ní ìlú jọ,

àti àwọn ẹni tí èmi ti pọ́n lójú.

7 Èmi yóò dá àwọn arọ sí fún èyí tókù,

èmi yóò sì sọ àwọn tí a lé kúrò ní ìlú di orílẹ̀-èdè alágbára.

Olúwa yóò sì jẹ ọba lórí wọn ní òkè ńlá Sioni

láti ìsinsin yìí lọ àti títí láéláé.

8 Ní ti ìwọ, ilé ìṣọ́ agbo àgùntàn,

odi alágbára ọmọbìnrin Sioni,

a ó mú ìjọba ìṣáájú padà bọ̀ sípò fún un yín;

ìjọba yóò sì wà sí ọ̀dọ̀ ọmọbìnrin Jerusalẹmu."

9 Kí ni ìwọ ha ń kígbe sókè sí nísinsin yìí?

Ǹjẹ́ ìwọ kò ní ọba bí?

Àwọn ìgbìmọ̀ rẹ ṣègbé bí?

Nítorí ìrora ti dì ọ́ mú bí obìnrin tí ń rọbí.

10 Máa yí síyìn-ín sọ́hùn-ún nínú ìrora,

ìwọ obìnrin Sioni,

bí ẹni tí ń rọbí,

nítorí nísinsin yìí ìwọ yóò jáde lọ kúrò ní ìlú,

ìwọ yóò sì máa gbé inú igbó.

Ìwọ yóò lọ sí Babeli;

níbẹ̀ ni ìwọ yóò sì ti rí ìgbàlà.

Níbẹ̀ ni Olúwa yóò ti rà ọ́ padà kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá rẹ.

11 Ṣùgbọ́n nísinsin yìí ọ̀pọ̀lọpọ̀ Orílẹ̀-èdè kó ara wọn jọ sí ọ.

Wọ́n sì wí pé, "Ẹ jẹ́ kí a sọ ọ́ di àìmọ́,

ẹ jẹ́ kí ojú wa kí ó wo Sioni!"

12 Ṣùgbọ́n wọn kò mọ

èrò inú Olúwa;

bẹ́ẹ̀ ni òye ìmọ̀ rẹ̀ kò yé wọn,

nítorí ó ti kó wọn jọ bí i ìtí sínú ìpakà.

13 "Dìde, kí ó sì máa pa ọkà ìwọ ọmọbìnrin Sioni,

nítorí èmi yóò sọ ìwo rẹ̀ di irin,

èmi yóò sì sọ pátákò rẹ̀ di idẹ

ìwọ yóò run ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè pátápátá."

Èmi yóò sì ya èrè wọn sọ́tọ̀ fún Olúwa

àti ọrọ̀ wọn sí Olúwa gbogbo ayé.

Estes versículos te tocaram? Ore agora!

+581 estão orando agora.

Junte-se à corrente de oração.