Amor de casal
O amor de casal é celebrado na Bíblia como dom sagrado. O Cântico dos Cânticos exalta a beleza do amor conjugal — íntimo, exclusivo e forte como a morte.
Gbé mi sí àyà rẹ bí èdìdì
bí èdìdì lé apá rẹ;
nítorí ìfẹ́ lágbára bí ikú,
ìjowú sì le bí isà òkú
jíjò rẹ̀ rí bí jíjò iná,
gẹ́gẹ́ bí ọ̀wọ́-iná Olúwa.
Omi púpọ̀ kò le paná ìfẹ́;
bẹ́ẹ̀ ni gbígbá omi kò le gbá a lọ.
Bí ènìyàn bá fún ìfẹ́,
ní gbogbo ọrọ̀ ilé rẹ̀,
a ó kẹ́gàn rẹ̀ pátápátá.
Ọ̀rẹ́
Ìwọ ti gba ọkàn mi, arábìnrin mi, ìyàwó mi;
ìwọ ti gba ọkàn mi
pẹ̀lú ìwò ẹ̀ẹ̀kan ojú rẹ,
pẹ̀lú ọ̀kan nínú ìlẹ̀kẹ̀ ọrùn rẹ.
Fi ìfẹnukonu ìfẹ́ kò mí ní ẹnu,
nítorí ìfẹ́ rẹ dára ju ọtí wáìnì lọ.
Òórùn ìkunra rẹ fanimọ́ra.
Orúkọ rẹ rí bí ìkunra tí a tú jáde
abájọ tí àwọn wúńdíá fi fẹ́ ọ.
Báwo ni o ti lẹ́wà tó, olólùfẹ́ mi!
Háà, báwo ni o ṣe lẹ́wà tó!
Ìwọ ní ojú ẹyẹlé.
Olólùfẹ́
Báwo ni o ṣe dára tó, olùfẹ́ mi!
Háà, báwo ni o ṣe wu ni!
Ibùsùn wa ní ìtura.
Olùfẹ́
Olúwa Ọlọ́run wí pé, "Kò dára kí ọkùnrin wà ní òun nìkan. Èmi yóò ṣe olùrànlọ́wọ́ tí ó rí bí i rẹ̀ fún un."
Olúwa Ọlọ́run sì dá obìnrin láti inú egungun tí ó yọ ní ìhà ọkùnrin náà, Ó sì mu obìnrin náà tọ̀ ọ́ wá.
Ọkùnrin náà sì wí pé,
"Èyí ni egungun láti inú egungun mi
àti ẹran-ara nínú ẹran-ara mi;
‘obìnrin’ ni a ó máa pè é,
nítorí a mú un jáde láti ara ọkùnrin."
Nítorí ìdí èyí, ọkùnrin yóò fi baba àti ìyá rẹ̀ sílẹ̀, yóò sì dàpọ̀ mọ́ aya rẹ̀, wọn yóò sì di ara kan.
Ẹni tí ó rí aya fẹ́, rí ohun rere,
o sì gba ojúrere lọ́dọ̀ Olúwa.
Jẹ́ kí orísun rẹ kí ó ní ìbùkún;
kí ìwọ ó sì máa yọ nínú aya ìgbà èwe rẹ.
Abo àgbọ̀nrín tó dára, ìgalà tí ó wu ni jọjọ,
jẹ́ kí ọmú rẹ̀ kí ó máa fi ayọ̀ fún ọ nígbà gbogbo,
kí o sì máa yọ̀ nínú ìfẹ́ rẹ̀ nígbàkígbà.
Ọmọ mi, èéṣe tí ìwọ ó fi máa yọ̀ nínú ìfẹ́ obìnrin panṣágà,
tí ìwọ ó sì fi dì mọ́ ìyàwó ẹlòmíràn?
Wọn kì í túnṣe méjì mọ́, ṣùgbọ́n ara kan. Nítorí náà, ohun tí Ọlọ́run bá ti so ṣọ̀kan, kí ẹnikẹ́ni má ṣe yà wọ́n."
Ìfẹ́ a máa mú sùúrù, ìfẹ́ a máa ṣeun, ìfẹ́ kì í ṣe ìlara, ìfẹ́ kì í fẹ̀, ìfẹ́ kì í sọ̀rọ̀ ìgbéraga. Ìfẹ́ kì í hùwà àìtọ́, kì í wá ohun ara rẹ̀ nìkan. Ìfẹ́ kì í bínú fùfù, ìfẹ́ kì í fi búburú ọmọ ẹnìkejì sínú. Inú ìfẹ́ kì í dùn sí àìṣòótọ́. Ṣùgbọ́n inú rẹ̀ a máa dùn nígbà gbogbo. A máa faradà ohun gbogbo sí òtítọ́, a máa gba ohun gbogbo gbọ́, a máa retí ohun gbogbo, a máa fàyàrán ohun gbogbo.
Bẹ́ẹ̀ ní ó tọ́ kí àwọn ọkùnrin máa fẹ́ràn aya wọn gẹ́gẹ́ bí ara àwọn fúnra wọn. Nítorí kò sì ẹnìkan tí ó ti kórìíra ara rẹ̀; bí kò ṣe pé kí ó máa bọ́ ọ kí ó sì máa ṣìkẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Kristi sì ti ń ṣe sí ìjọ.
Ṣùgbọ́n kí olúkúlùkù yín fẹ́ràn aya rẹ̀, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ bí òun fúnra rẹ̀; kí aya kí ó sì bọ̀wọ̀ fún ọkọ rẹ̀.
Àti borí gbogbo nǹkan wọ̀nyí, ẹ gbé ìfẹ́ wọ̀, tí í ṣe àmùrè ìwà pípé.
Ẹni méjì sàn ju ẹnìkan,
nítorí wọ́n ní èrè rere fún làálàá wọn.
Tí ọ̀kan bá ṣubú lulẹ̀,
ọ̀rẹ́ rẹ̀ le è ràn án lọ́wọ́ kí ó fà á sókè,
ṣùgbọ́n ìyọnu ni fún ọkùnrin náà tí ó ṣubú
tí kò sì ní ẹni tí ó le è ràn án lọ́wọ́!
Àti pẹ̀lú pé, bí ẹni méjì bá sùn pọ̀, wọn yóò móoru.
Ṣùgbọ́n báwo ni ẹnìkan ṣe le è dá nìkan móoru?
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, a le è kojú ogun ẹnìkan,
àwọn méjì le è gbìjà ara wọn,
ìkọ́ okùn mẹ́ta kì í dùn ún yára fà já.
Ọlọ́run kò ha ti ṣe wọ́n ní ọ̀kan? Ni ara àti ni ẹ̀mí tirẹ̀ ni. Èéṣe tí Ọlọ́run da yín lọ́kàn? Kí òun bá à lè wá irú-ọmọ bí ti Ọlọ́run. Nítorí náà, ẹ tọ́jú ẹ̀mí yín, ẹ má sì ṣe hùwà ẹ̀tàn sí aya èwe yín.
Bí ọkùnrin kan bá ṣẹ̀ṣẹ̀ gbéyàwó, o kò gbọdọ̀ ran lọ sí ogun tàbí kí ó ní iṣẹ́ kan láti ṣe. Ó ní láti ní òmìnira fún ọdún kan kí ó dúró sílé kí ó sì mú inú dídùn bá ìyàwó rẹ̀ tí ó fẹ́.