1 Orin, àwọn orin tí í ṣe orin Solomoni.
2 Fi ìfẹnukonu ìfẹ́ kò mí ní ẹnu,
nítorí ìfẹ́ rẹ dára ju ọtí wáìnì lọ.
3 Òórùn ìkunra rẹ fanimọ́ra.
Orúkọ rẹ rí bí ìkunra tí a tú jáde
abájọ tí àwọn wúńdíá fi fẹ́ ọ.
4 Fà mí lọ pẹ̀lú rẹ, kí a lọ kíákíá
ọba ti mú mi wá sínú yàrá rẹ̀.
Àwa yọ̀ inú wa sì dùn sí ọ;
a gbé ìfẹ́ rẹ ga ju ọtí wáìnì lọ.
Wọ́n fẹ́ ọ nítòótọ́!
5 Èmi dúdú mo sì ní ẹwà.
Ẹ̀yin ọmọbìnrin Jerusalẹmu
dúdú bí àgọ́ ìlú Kedari,
bí aṣọ títa ti Solomoni.
6 Má ṣe wò mí nítorí wí pé mo dúdú,
nítorí oòrùn mú mi dúdú,
ọmọkùnrin ìyá mi bínú sí mi
ó sì fi mí ṣe olùtọ́jú ọgbà àjàrà;
ọgbà àjàrà tèmi ni èmi kò tọ́jú.
7 Wí fún mi, ìwọ ẹni tí ọkàn mí fẹ́,
níbo ni ìwọ ń da agbo ẹran lọ.
Níbi tí ìwọ mú agbo ẹran rẹ sinmi ní ọ̀sán,
kí ni ìdí tí èmi yóò fi jẹ́ obìnrin asán
ní ẹ̀bá agbo ẹran àwọn ọ̀rẹ́ rẹ.
8 Bí ìwọ kò bá mọ̀,
ìwọ arẹwà jùlọ nínú àwọn obìnrin.
Bá ọ̀nà tí agbo ẹran rìn lọ,
kí o sì bọ́ àwọn ọmọ ewúrẹ́ rẹ.
Ní ẹ̀bá àgọ́ àwọn olùṣọ́-àgùntàn.
9 Olùfẹ́ mi,
mo fi ọ́ wé ẹṣin mi nínú kẹ̀kẹ́ Farao.
10 Ẹ̀rẹ̀kẹ́ rẹ dára ní ohun ọ̀ṣọ́,
ọrùn rẹ sì yẹ ọ̀ṣọ́ ìlẹ̀kẹ̀.
11 A ó fi wúrà ṣe òrùka etí fún ọ,
a ó fi fàdákà ṣe ìlẹ̀kẹ̀.
12 Nígbà tí ọba wà ní orí ìjókòó rẹ̀,
òróró ìkunra mi tú òórùn jáde.
13 Ìdì òjìá ni olùfẹ́ mi jẹ sí mi,
òun ó sinmi lé àárín ọmú mi.
14 Bí ìdì ìtànná Henina ni olùfẹ́ mi rí sí mi
láti inú ọgbà àjàrà ti En-Gedi.
15 Báwo ni o ti lẹ́wà tó, olólùfẹ́ mi!
Háà, báwo ni o ṣe lẹ́wà tó!
Ìwọ ní ojú ẹyẹlé.
16 Báwo ni o ṣe dára tó, olùfẹ́ mi!
Háà, báwo ni o ṣe wu ni!
Ibùsùn wa ní ìtura.
17 Ìtànṣán ilé wa jẹ́ ti igi kedari
ẹkẹ́ ilé wa jẹ́ ti igi firi.