1 Ènìyàn tí kò ba ni rẹ́ a máa lépa ìmọ̀ ara rẹ̀;
ó kọjú ìjà sí gbogbo ìdájọ́ òdodo.
2 Aláìgbọ́n kò rí inú dídùn sí òye
ṣùgbọ́n ó ní inú dídùn sí sísọ èrò tirẹ̀.
3 Nígbà ti ènìyàn búburú dé ni ẹ̀gàn dé,
nígbà ti ẹ̀gàn dé ni ìtìjú dé.
4 Ọ̀rọ̀ ẹnu ènìyàn jẹ́ omi jíjìn,
ṣùgbọ́n orísun ọgbọ́n jẹ́ odò tí ń sàn.
5 Kò dára kí ènìyàn ṣe ojúsàájú fún ènìyàn búburú
tàbí kí a fi ìdájọ́ òdodo du aláìṣẹ̀.
6 Ètè aláìgbọ́n dá ìjà sílẹ̀
ẹnu rẹ̀ sì ń ṣokùnfà ẹgba.
7 Ẹnu aláìgbọ́n ni ó ba tirẹ̀ jẹ́,
ètè rẹ̀ sì jẹ́ ìdẹ̀kùn fún ọkàn rẹ̀.
8 Ọ̀rọ̀ olófòófó dàbí oúnjẹ àdídùn;
wọ́n a sì wọ ìsàlẹ̀ inú lọ.
9 Ẹni tí kò ṣe déédé nínú iṣẹ́ rẹ̀
arákùnrin ló jẹ́ fún apanirun.
10 Orúkọ Olúwa, ilé ìṣọ́ agbára ni;
olódodo sá wọ inú rẹ̀, ó sì rí ìgbàlà.
11 Ọ̀rọ̀ olówó ni ìlú olódi wọn;
wọ́n rò ó bí i wí pé odi tí kò ṣe é gùn ni.
12 Ṣáájú ìṣubú ọkàn ènìyàn a kọ́kọ́ máa gbéraga,
ṣùgbọ́n ìrẹ̀lẹ̀ ni ó máa ń ṣáájú ọlá.
13 Ẹni tí ó ń fèsì kí ó tó gbọ́,
èyí ni ìwà òmùgọ̀ àti ìtìjú rẹ̀.
14 Ọkàn ènìyàn a máa gbé e ró nígbà àìsàn,
ṣùgbọ́n ta ni ó le forí ti ọkàn tí ó rẹ̀wẹ̀sì.