Publicidade

Provérbios 16

1 Ti ènìyàn ni ìgbèrò inú ọkàn

ṣùgbọ́n láti ọ̀dọ̀ Olúwa ni ìdáhùn ahọ́n ti ń wá.

2 Gbogbo ọ̀nà ènìyàn ni ó dàbí i pé ó dára lójú ara rẹ̀

ṣùgbọ́n Olúwa ló ń díwọ̀n èrò inú ọkàn.

3 Fi ohun gbogbo tí o bá ṣe lé Olúwa lọ́wọ́,

èrò rẹ yóò sì ṣe é ṣe.

4 Olúwa ti ṣe ohun gbogbo láti mú kí ó rí bí ó ṣe fẹ́

kódà ènìyàn búburú fún ọjọ́ ìpọ́njú.

5 Olúwa kórìíra gbogbo ẹni tí ń gbéraga lọ́kàn rẹ̀

mọ èyí dájú pé wọn kò ní lọ láìjìyà.

6 Nípasẹ̀ ìfẹ́ àti òtítọ́ a ṣe ètùtù ẹ̀ṣẹ̀

nípasẹ̀ ìbẹ̀rù Olúwa ènìyàn sá fún ibi.

7 Nígbà tí ọ̀nà ènìyàn bá tẹ́ Olúwa lọ́rùn,

yóò mú kí àwọn ọ̀tá rẹ̀ gàn án bá a gbé ní àlàáfíà.

8 Ó sàn kí ó kéré pẹ̀lú òdodo

ju èrè púpọ̀ pẹ̀lú èrú lọ.

9 Ènìyàn a máa pète ọ̀nà ara rẹ̀ lọ́kàn an rẹ̀

ṣùgbọ́n Olúwa ní í pinnu ìgbésẹ̀ rẹ̀.

10 Ètè ọba a máa sọ̀rọ̀ nípa àṣẹ sí i

ẹnu rẹ̀ kò gbọdọ̀ ṣèké.

11 Òdínwọ̀n àti òsùwọ̀n òtítọ́ wá láti ọ̀dọ̀ Olúwa;

gbogbo wíwúwo àpò jẹ́ láti ọwọ́ rẹ̀.

12 Àwọn ọba kórìíra ìwà àìtọ́

nítorí òdodo ní í fi ìdí ìtẹ́ múlẹ̀.

13 Àwọn ọba ní inú dídùn sí ètè tí ń ṣọ òtítọ́,

wọ́n sì fẹ́ ẹni tí ń sọ̀rọ̀ òtítọ́.

14 Ìránṣẹ́ ikú ni ìbínú ọba jẹ́

ṣùgbọ́n ọlọ́gbọ́n ènìyàn yóò tù ú nínú.

15 Nígbà tí ojú ọba bá túká, ó túmọ̀ sí ìyè;

ojúrere rẹ̀ dàbí i ṣíṣú òjò ní ìgbà òjò.

16 Ó ti dára tó láti ní ọgbọ́n ju wúrà lọ

àti láti yan òye dípò o fàdákà!

17 Òpópó ọ̀nà àwọn ẹni dídúró ṣinṣin yàgò fún ibi,

ẹni tí ó ṣọ́ ọ̀nà rẹ̀, ṣọ́ ẹnu ara rẹ̀.

18 Ìgbéraga ní í ṣáájú ìparun,

agídí ọkàn ní í ṣáájú ìṣubú.

19 Ó sàn láti jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ ọkàn láàrín àwọn olùpọ́njú

jù láti máa pín ìpín pẹ̀lú àwọn agbéraga.

20 Ẹnikẹ́ni tí ó bá tẹ̀lé ẹ̀kọ́ yóò rí ìre,

ìbùkún sì ni fún ẹni tí ó gbẹ́kẹ̀lé Olúwa.

21 Àwọn tí ó gbọ́n nínú ọkàn là ń pè ní olóye

ọ̀rọ̀ ìtura sì ń mú ẹ̀kọ́ gbèrú.

22 Òye jẹ́ orísun ìyè fún àwọn tí ó ní i,

ṣùgbọ́n ìwà òmùgọ̀ ń kó ìyà jẹ aláìgbọ́n.

23 Ọkàn ọlọ́gbọ́n ènìyàn a máa ṣọ́ ẹnu rẹ̀

ètè rẹ̀ sì ń mú kí ẹ̀kọ́ dàgbà.

24 Ọ̀rọ̀ ìtura dàbí afárá oyin

ó dùn fún ọkàn, ó sì fi ìlera fún egungun.

25 Ọ̀nà kan tí ó dàbí i pé ó dára lójú ènìyàn

ṣùgbọ́n ní ìgbẹ̀yìn a ṣokùnfà ikú.

26 Ọkàn alágbàṣe ń ṣiṣẹ́ fún ara rẹ̀;

nítorí ebi rẹ̀ mú kí ó máa ṣiṣẹ́ lọ.

27 Ènìyàn búburú ń pète

ọ̀rọ̀ rẹ̀ sì dàbí i iná tí ń jóni.

28 Aláyídáyidà ènìyàn dá ìjà sílẹ̀

olófòófó a sì máa pín ọ̀rẹ́ kòríkòsùn ní yà.

29 Oníjàgídíjàgan ènìyàn tan aládùúgbò rẹ̀

ó sì mú un sọ̀kalẹ̀ lọ sí ọ̀nà tí kò dára.

30 Ẹni tí ń ṣẹ́jú ń pètekéte;

ẹni tí ó ṣu ẹnu jọ ń pète aburú.

31 Adé ògo ni ewú orí jẹ́,

ìgbé ayé òdodo ní í mú ni dé bẹ̀.

32 Ó sàn láti jẹ́ onísùúrù ju ajagun ènìyàn lọ,

ẹni tí ó pa ìbínú mọ́ra ju ajagun ṣẹ́gun ìlú lọ.

33 A ṣẹ́ kèké si ìṣẹ́po aṣọ,

ṣùgbọ́n gbogbo ìdájọ́ rẹ̀ wá láti ọ̀dọ̀ Olúwa.

Veja também

Publicidade
Bíblia Online Bíblia Online

Bíblia Online • Versão: 2026-06-15_21-32-39-