Publicidade

Provérbios 29

1 Ẹni tí ó sì ń ṣorí kunkun lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìbáwí

yóò parun lójijì láìsí àtúnṣe.

2 Nígbà tí olódodo bá ń gbilẹ̀, àwọn ènìyàn a yọ̀

nígbà tí ènìyàn búburú ń ṣàkóso, àwọn ènìyàn ń kórìíra.

3 Ènìyàn tí ó fẹ́ràn ọgbọ́n mú kí baba rẹ̀ láyọ̀

ṣùgbọ́n ẹni ti ń bá panṣágà kẹ́gbẹ́ ba ọrọ̀ ọ rẹ̀ jẹ́.

4 Nípa ìdájọ́ òdodo ni ọba fi í mú ìlú tòrò nini,

ṣùgbọ́n èyí tí ń ṣe ojúkòkòrò àbẹ̀tẹ́lẹ̀ fà á lulẹ̀.

5 Ẹnikẹ́ni tí ó bá tan aládùúgbò rẹ̀

ó ń dẹ àwọ̀n de ẹsẹ̀ ẹ rẹ̀.

6 Ẹ̀ṣẹ̀ ènìyàn ibi ni ó jẹ́ ìdẹ̀kùn rẹ̀

ṣùgbọ́n olódodo le è kọrin kí ó sì máa yọ̀.

7 Olódodo ń máa ro ọ̀rọ̀ tálákà,

ṣùgbọ́n ènìyàn búburú kò sú sí i láti rò ó.

8 Àwọn ẹlẹ́yà a máa ru ìlú sókè,

ṣùgbọ́n àwọn ọlọ́gbọ́n ènìyàn máa ń mú ìbínú kúrò.

9 Bí ọlọ́gbọ́n ènìyàn bá lọ sí ilé ẹjọ́ pẹ̀lú aláìgbọ́n

aláìgbọ́n a máa bínú a sì máa jà, kò sì ní sí àlàáfíà.

10 Àwọn tí ó ń tàjẹ̀ sílẹ̀ kò rí ẹni dídúró ṣinṣin

wọ́n sì ń wá ọ̀nà láti pa olódodo.

11 Aláìgbọ́n ènìyàn fi gbogbo ẹnu rẹ̀ bínú

ṣùgbọ́n ọlọ́gbọ́n ènìyàn a máa kó ìbínú rẹ̀ ní ìjánu.

12 Bí olórí bá fetí sí irọ́,

gbogbo àwọn ìjòyè rẹ̀ a di ènìyàn búburú lójú rẹ̀.

13 Tálákà ènìyàn àti aninilára jọ ní àbùdá yìí,

Olúwa jẹ́ kí ojú àwọn méjèèjì máa ríran.

14 Bí ọba kan bá ń ṣe ìdájọ́ tálákà pẹ̀lú òtítọ́

ìtẹ́ ìjọba rẹ yóò fìdímúlẹ̀ nígbà gbogbo.

15 Ọ̀pá ìbániwí ń fún ni ní ọgbọ́n

ṣùgbọ́n ọmọ tí a fi sílẹ̀ fúnra rẹ̀ a dójútì ìyá rẹ̀.

16 Nígbà tí ènìyàn búburú ń gbilẹ̀, bẹ́ẹ̀ náà ni ẹ̀ṣẹ̀ ń gbilẹ̀

ṣùgbọ́n olódodo yóò rí ìṣubú wọn.

17 Bá ọmọ rẹ wí, yóò sì fún ọ ní àlàáfíà

yóò sì mú inú dídùn wá sí inú ọkàn rẹ.

18 Níbi tí kò ti sí ìfihàn, àwọn ènìyàn a gbé ìgbé ayé àìbìkítà,

ṣùgbọ́n ìbùkún ní fún àwọn tí ń pa òfin mọ́.

19 A kò le fi ọ̀rọ̀ lásán kìlọ̀ fún ìránṣẹ́

bí ó tilẹ̀ yé e, kò ní kọbi ara sí i.

20 Ǹjẹ́ ó rí ènìyàn tí ń kánjú sọ̀rọ̀?

Ìrètí wà fún aláìgbọ́n jù ú lọ.

21 Bí ènìyàn kan bá kẹ́ ìránṣẹ́ rẹ̀ lákẹ̀ẹ́jù láti kékeré

yóò mú ìbànújẹ́ wá ní ìgbẹ̀yìn.

22 Oníbìínú ènìyàn a ru ìjà sókè,

onínú-fùfù ènìyàn a sì máa dá ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀ṣẹ̀.

23 Ìgbéraga ènìyàn a máa sọ ọ́ di ẹni ilẹ̀

ṣùgbọ́n onírẹ̀lẹ̀ ènìyàn a máa gba iyì kún iyì.

24 Ẹni tí ó ń kó ẹgbẹ́, olè kórìíra ọkàn ara rẹ̀,

ó ń gbọ́ èpè olóhun kò sì le è fọhùn.

25 Ìbẹ̀rù ènìyàn kan yóò sì di ìdẹ̀kùn

ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó bẹ̀rù Olúwa wà láìléwu.

26 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni ń wá ojúrere alákòóso,

ṣùgbọ́n láti ọ̀dọ̀ Olúwa ni ènìyàn tí ń gba ìdájọ́ òdodo.

27 Olódodo kórìíra àwọn aláìṣòótọ́:

ènìyàn búburú kórìíra olódodo.

Veja também

Publicidade
Bíblia Online Bíblia Online

Bíblia Online • Versão: 2026-06-15_21-32-39-