25 Agbára àti ọlá ni ó wò ọ́ láṣọ
ó le fi ọjọ́ iwájú rẹ́rìn-ín.
26 A sọ̀rọ̀ pẹ̀lú ọgbọ́n
ìkọ́ni òtítọ́ sì ń bẹ létè e rẹ̀
27 Ó ń bojútó gbogbo ètò ilé rẹ̀
kì í sì í jẹ oúnjẹ ìmẹ́lẹ́.
28 Àwọn ọmọ rẹ̀ dìde wọ́n sì pè é ní alábùkún
ọkọ rẹ̀ pẹ̀lú ń gbóríyìn fún un.
29 "Ọ̀pọ̀lọpọ̀ obìnrin ní ń ṣe nǹkan ọlọ́lá
ṣùgbọ́n ìwọ ju gbogbo wọn lọ."
30 Ojú dáradára a máa tan ni, ẹwà sì jẹ́ asán
nítorí obìnrin tí ó bẹ̀rù Olúwa yẹ kí ó gba oríyìn.