4 Nígbà náà ni Josẹfu wí fún àwọn arákùnrin rẹ̀ pé, "Ẹ súnmọ́ ọ̀dọ̀ mi." Nígbà tí wọ́n sì ti ṣe bẹ́ẹ̀, ó wí pé, "Èmi ni Josẹfu arákùnrin yín tí ẹ tà sí ilẹ̀ Ejibiti! 5 Ṣùgbọ́n báyìí, ẹ má ṣe banújẹ́, ẹ má sì ṣe bínú sí ara yín ní títà tí ẹ tà mí sí ìhín, nítorí, ọ̀nà àti gba ẹ̀mí yín là ni Ọlọ́run ṣe rán mi sí ìhín ṣáájú yín.
Publicidade