11 Tìrẹ Olúwa ni títóbi àti agbára pẹ̀lú ìyìn
àti ọláńlá àti dídán,
nítorí tí gbogbo nǹkan ní ọ̀run àti ayé jẹ́ tìrẹ.
Tìrẹ Olúwa ni ìjọba;
a gbé ọ ga gẹ́gẹ́ bí orí lórí ohun gbogbo.
12 Ọlá àti ọ̀wọ̀ wá láti ọ̀dọ̀ Rẹ;
ìwọ ni alákòóso gbogbo nǹkan.
Ní ọwọ́ rẹ ni ipá àti agbára wà láti gbéga àti
láti fi agbára fún ohun gbogbo.
14 "Ṣùgbọ́n ta ni èmi, àti ta ni àwọn ènìyàn mi, tí a fi lè ṣe ìrànlọ́wọ́ tinútinú bí irú èyí? Gbogbo nǹkan wá láti ọ̀dọ̀ rẹ ní ti wá, àwa sì ti fífún ọ láti ara ohun tí ó wá láti ọwọ́ rẹ. 15 Àwa jẹ́ àjèjì àti àlejò ní ojú rẹ gẹ́gẹ́ bí baba ńlá a wa, àwọn ọjọ́ wa lórí ilẹ̀ ayé rí bí òjìji láìsí ìrètí.