12 Ṣùgbọ́n níbo ni á ó gbé wá ọgbọ́n rí,
níbo sì ni òye ń gbe?
13 Ènìyàn kò mọ iye rẹ̀,
bẹ́ẹ̀ ni a kò le è rí i ní ilẹ̀ àwọn alààyè.
14 Ọ̀gbun wí pé, "Kò sí nínú mi";
omi òkun sì wí pé, "Kò si nínú mi."
15 A kò le è fi wúrà rà á,
bẹ́ẹ̀ ni a kò le è fi òsùwọ̀n wọn fàdákà ní iye rẹ̀.
16 A kò le è fi wúrà Ofiri, tàbí òkúta óníkìsì iyebíye,
tàbí òkúta safire díye lé e.
17 Wúrà àti òkúta kristali kò tó ẹgbẹ́ rẹ̀;
bẹ́ẹ̀ ni a kò le è fi ohun èlò wúrà ṣe pàṣípàrọ̀ rẹ̀.
18 A kò lè dárúkọ iyùn tàbí òkúta jasperi;
iye ọgbọ́n sì ju iyùn lọ.
19 Òkúta topasi ti Kuṣi kò tó ẹgbẹ́ rẹ̀;
bẹ́ẹ̀ ni a kò le fi wúrà dáradára díwọ̀n iye rẹ̀.
20 Níbo ha ni ọgbọ́n ti jáde wá?
Tàbí níbo ni òye ń gbé?
21 A rí i pé, ó fi ara sinko kúrò ní ojú àwọn alààyè gbogbo,
ó sì fi ara sin fún ẹyẹ ojú ọ̀run.
22 Ibi ìparun àti ikú wí pé,
àwa ti fi etí wa gbúròó rẹ̀.