Ìbùkún àlùfáà
22 Olúwa sọ fún Mose pé, 23 "Sọ fún Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ pé, ‘Báyìí ni kí ẹ ṣe máa súre fún àwọn ọmọ Israẹli. Ẹ sọ fún wọn pé,
24 " ‘ "Kí Olúwa bùkún un yín,
kí ó sì pa yín mọ́.
25 Kí Olúwa kí o mú ojú rẹ̀ kí ó mọ́lẹ̀ sí i yín lára.
Kí ó sì ṣàánú fún un yín.
26 Kí Olúwa bojú wò yín,
kí ó sì fún un yín ní àlàáfíà." ’
27 "Báyìí ni wọn ó ṣe fi orúkọ mi sára àwọn ọmọ Israẹli, Èmi ó sì bùkún wọn."