Publicidade

Isaías 64

1 Ìwọ ìbá fa ọ̀run ya kí o sì sọ̀kalẹ̀ wá,

tí àwọn òkè ńlá yóò fi wárìrì níwájú rẹ!

2 Gẹ́gẹ́ bí ìgbà tí iná mú ẹ̀ka igi jó

tí ó sì mú kí omi ó hó,

sọ̀kalẹ̀ wá kí orúkọ rẹ le di mí mọ̀ fún àwọn ọ̀tá rẹ

kí o sì jẹ́ kí àwọn orílẹ̀-èdè kí ó wárìrì níwájú rẹ!

3 Nítorí nígbà tí o bá ṣe àwọn ohun ẹ̀rù tí àwa kò nírètí,

o sọ̀kalẹ̀ wá, àwọn òkè ńlá sì wárìrì níwájú rẹ̀.

4 Láti ìgbà àtijọ́ kò sí ẹni tí ó gbọ́ rí

kò sí etí kan tí ó gbọ́ ọ,

kò sí ojú tí ó tí ì rí Ọlọ́run mìíràn lẹ́yìn rẹ,

tí ó máa ń ṣe nǹkan lórúkọ àwọn tí ó dúró dè é.

5 Ìwọ a máa wá fún ìrànlọ́wọ́ àwọn tí wọn

ń fi ayọ̀ ṣe ohun tó tọ́,

tí ó rántí ọ̀nà rẹ.

Ṣùgbọ́n nígbà tí a bẹ̀rẹ̀ sí dẹ́ṣẹ̀ sí wọn,

inú bí ọ.

Báwo ni a ó ṣe gbà wá là?

6 Gbogbo wa ti dàbí ẹnìkan tí ó jẹ́ aláìmọ́,

gbogbo òdodo wa sì dàbí èkísà ẹlẹ́gbin;

gbogbo wa kákò bí ewé,

àti bí afẹ́fẹ́, ẹ̀ṣẹ̀ wa ti gbá wa lọ kúrò.

7 Ẹnikẹ́ni kò pe orúkọ rẹ

tàbí kí ó gbìyànjú láti dì ẹ́ mú;

nítorí ìwọ ti fi ojú rẹ pamọ́ fún wa

ó sì jẹ́ kí àwa ṣòfò dànù nítorí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa.

8 Síbẹ̀síbẹ̀, Olúwa, ìwọ ni Baba wa.

Àwa ni amọ̀, ìwọ ni amọ̀kòkò;

gbogbo wa jẹ́ iṣẹ́ ọwọ́ rẹ.

9 Má ṣe bínú kọjá ààlà, ìwọ Olúwa,

má ṣe rántí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wa títí láé.

Jọ̀wọ́, bojú wò wá, ni a gbàdúrà,

nítorí ènìyàn rẹ ni gbogbo wa.

10 Àwọn ìlú mímọ́ rẹ ti di aṣálẹ̀;

Sioni pàápàá di aṣálẹ̀, Jerusalẹmu di ahoro.

11 Tẹmpili mímọ́ ológo wa, níbi tí àwọn baba wa ti yìn ọ́,

ni a ti fi iná sun,

àti ohun gbogbo tí í ṣe ìṣúra wa ti dahoro.

12 Lẹ́yìn gbogbo nǹkan wọ̀nyí, Olúwa, ìwọ ó ha sì tún fi ara rẹ pamọ́ bí?

Ìwọ ó ha dákẹ́ kí o sì fìyà jẹ wá kọjá ààlà bí?

Veja também

Publicidade
Bíblia Online Bíblia Online

Bíblia Online • Versão: 2026-06-15_21-32-39-