Pular para o conteúdo
Publicidade

Saamu 91

1 Ẹni tí ó gbé ibi ìkọ̀kọ̀ Ọ̀gá-ògo

ni yóò sinmi ní ibi òjìji Olódùmarè.

2 Èmi yóò sọ nípa ti Olúwa pé,

"Òun ni ààbò àti odi mi,

Ọlọ́run mi, ẹni tí èmi gbẹ́kẹ̀lé".

3 Nítòótọ́ òun yóò gbà mí nínú

ìdẹ̀kùn àwọn pẹyẹpẹyẹ

àti nínú àjàkálẹ̀-ààrùn búburú.

4 Òun yóò fi ìyẹ́ rẹ̀ bò mí,

àti ni abẹ́ ìyẹ́ rẹ̀ ni èmi yóò ti rí ààbò;

òtítọ́ rẹ̀ ni yóò ṣe ààbò àti odi mi.

5 Ìwọ kì yóò bẹ̀rù nítorí ẹ̀rù òru,

tàbí fún ọfà tí ń fò ní ọ̀sán,

6 tàbí fún àjàkálẹ̀-ààrùn tí ń rìn kiri ní òkùnkùn,

tàbí fún ìparun tí ń rìn kiri ní ọ̀sán gangan.

7 Ẹgbẹ̀rún (1,000) yóò ṣubú ní ẹ̀gbẹ́ rẹ,

ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ,

ṣùgbọ́n kì yóò súnmọ́ ọ̀dọ̀ rẹ.

8 Ìwọ yóò máa wò ó pẹ̀lú ojú rẹ

àti wo ìjìyà àwọn ẹni búburú.

9 Nítorí ìwọ fi Olúwa ṣe ààbò rẹ,

ìwọ fi Ọ̀gá-ògo ṣe ibùgbé rẹ.

10 Búburú kan ki yóò ṣubú lù ọ́,

Bẹ́ẹ̀ ni ààrùnkárùn kì yóò súnmọ́ ilé rẹ.

11 91.11-12: Mt 4.6; Lk 4.10-11. Nítorí yóò fi àṣẹ fún àwọn angẹli nípa tìrẹ

láti pa ọ́ mọ́ ní gbogbo ọ̀nà rẹ;

12 wọn yóò gbé ọ sókè ní ọwọ́ wọn,

nítorí kí ìwọ má ba à fi ẹsẹ̀ rẹ gún òkúta.

13 91.13: Lk 10.19. Ìwọ yóò rìn lórí kìnnìún àti paramọ́lẹ̀;

ìwọ yóò tẹ kìnnìún ńlá àti ejò ńlá ni ìwọ yóò fi ẹsẹ̀ tẹ̀ mọ́lẹ̀.

14 "Nítorí ti ìfẹ́ rẹ sí mi, èmi yóò gbà ọ́;

èmi yóò pa ọ́ mọ́, nítorí ìwọ jẹ́wọ́ orúkọ mi.

15 Òun yóò pè mí, èmi yóò sì dá a lóhùn;

èmi yóò wà pẹ̀lú rẹ̀ nínú ìpọ́njú,

èmi yóò gbà á, èmi yóò sì bu ọlá fún un.

16 Pẹ̀lú ẹ̀mí gígùn ni èmi yóò fi tẹ́ ẹ lọ́rùn,

èmi yóò sì fi ìgbàlà mi hàn án."

Estes versículos te tocaram? Ore agora!

+581 estão orando agora.

Junte-se à corrente de oração.