Publicidade

Salmos 100

Saamu. Fún ọpẹ́.

1 Ẹ hó ìhó ayọ̀ sí Olúwa, gbogbo ayé.

2 Ẹ fi ayọ̀ sin Olúwa,

ẹ wá síwájú rẹ̀ pẹ̀lú orin dídùn

3 Olúwa Ọlọ́run ni ó dá wa,

kí ẹ̀yin kí ó mọ̀ pé

tirẹ̀ ni àwa, àwa ní ènìyàn rẹ̀

àti àgùntàn pápá rẹ̀.

4 Ẹ lọ sí ẹnu-ọ̀nà rẹ̀ pẹ̀lú ọpẹ́

àti sí àgbàlá rẹ̀ pẹ̀lú ìyìn;

ẹ fi ọpẹ́ àti ìyìn fún orúkọ rẹ̀.

5 Nítorí tí Olúwa pọ̀ ní oore

ìfẹ́ rẹ̀ sì wà títí láé;

àti òtítọ́ rẹ̀ láti ìran de ìran.

Veja também

Publicidade
Bíblia Online Bíblia Online

Bíblia Online • Versão: 2026-06-15_21-32-39-