Publicidade

Salmos 105

1 Ẹ fi ọpẹ́ fún Olúwa, ké pe orúkọ rẹ̀,

jẹ́ kí a mọ ohun tí ó ṣe láàrín àwọn orílẹ̀-èdè.

2 Kọrin sí i, kọrin ìyìn sí i;

sọ ti iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ gbogbo.

3 Ṣògo nínú orúkọ mímọ́ rẹ̀,

jẹ́ kí ọkàn àwọn tí ń wá Olúwa kí ó yọ̀.

4 Olúwa àti ipá rẹ̀;

wa ojú rẹ̀ nígbà gbogbo.

5 Rántí àwọn ìyanu tí ó ti ṣe,

ìyanu rẹ̀, àti ìdájọ́ tí ó sọ,

6 ẹ̀yin ìran Abrahamu ìránṣẹ́ rẹ̀,

ẹ̀yin ọmọkùnrin Jakọbu, àyànfẹ́ rẹ̀.

7 Òun ni Olúwa Ọlọ́run wa:

ìdájọ́ rẹ̀ wà ní gbogbo ayé.

8 Ó rántí májẹ̀mú rẹ̀ láéláé,

ọ̀rọ̀ tí ó pàṣẹ, fún ẹgbẹẹgbẹ̀rún ìran,

9 májẹ̀mú tí ó dá pẹ̀lú Abrahamu,

ìbúra tí ó ṣe pẹ̀lú fún Isaaki.

10 Ó ṣe ìdánilójú u rẹ̀ fún Jakọbu gẹ́gẹ́ bí àṣẹ,

sí Israẹli, gẹ́gẹ́ bi májẹ̀mú ayérayé:

11 "Fún ìwọ ni èmi ó fún ní ilẹ̀ Kenaani

gẹ́gẹ́ bí ìpín tí ìwọ ó jogún."

12 Nígbà tí wọn kéré níye,

wọ́n kéré jọjọ, àti àwọn àjèjì níbẹ̀

13 wọ́n rìn kiri láti orílẹ̀-èdè sí orílẹ̀-èdè,

láti ìjọba kan sí èkejì.

14 Kò gba ẹnikẹ́ni láààyè láti pọ́n wọn lójú;

ó fi ọba bú nítorí tiwọn:

15 "Má ṣe fọwọ́ kan ẹni àmì òróró mi; má sì ṣe wòlíì mi níbi."

16 Ó pe ìyàn sórí ilẹ̀ náà

ó sì pa gbogbo ìpèsè oúnjẹ wọn run;

17 Ó sì rán ọkùnrin kan síwájú wọn

Josẹfu tí a tà gẹ́gẹ́ bí ẹrú.

18 Wọn fi ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀ bọ ẹsẹ̀ rẹ̀

a gbé ọrùn rẹ̀ sínú irin,

19 títí ọ̀rọ̀ tí ó sọtẹ́lẹ̀ fi ṣẹ

títí ọ̀rọ̀ Olúwa fi dá a láre.

20 Ọba ránṣẹ́ lọ tú u sílẹ̀

àwọn aláṣẹ ènìyàn tú u sílẹ̀

21 Ó fi jẹ olúwa lórí ilẹ̀ rẹ̀,

aláṣẹ lórí ohun gbogbo tí ó ní,

22 gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ rẹ̀, kí ó máa

ṣe àkóso àwọn ọmọ-aládé

kí ó sì kọ́ àwọn àgbàgbà rẹ̀ ní ọgbọ́n.

23 Israẹli wá sí Ejibiti;

Jakọbu sì ṣe àtìpó ní ilé Hamu.

24 Olúwa, sì mú àwọn ọmọ rẹ̀ bí sí i

ó sì mú wọn lágbára jù

àwọn ọ̀tá wọn lọ

25 Ó yí wọn lọ́kàn padà láti kórìíra àwọn ènìyàn

láti ṣe àrékérekè sí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀.

26 Ó rán Mose ìránṣẹ́ rẹ̀,

àti Aaroni tí ó ti yàn.

27 Wọ́n ń ṣe iṣẹ́ ìyanu láàrín wọn

ó ṣe iṣẹ́ ìyanu ní Hamu.

28 Ó rán òkùnkùn, o sì mú ilẹ̀ ṣú

wọn kò sì sọ̀rọ̀-òdì sí ọ̀rọ̀ rẹ̀.

29 Ó sọ omi wọn di ẹ̀jẹ̀,

ó pa ẹja wọn.

30 Ilẹ̀ mú ọ̀pọ̀lọ́ jáde wá,

èyí tí ó lọ sí ìyẹ̀wù àwọn ọba wọn.

31 Ó sọ̀rọ̀, onírúurú eṣinṣin sì dìde,

ó sì hu kantíkantí ní ilẹ̀ wọn

32 Ó sọ òjò di yìnyín,

àti ọ̀wọ́-iná ní ilẹ̀ wọn;

33 Ó lu àjàrà wọn àti igi ọ̀pọ̀tọ́ wọn

ó sì dá igi orílẹ̀-èdè wọn.

34 Ó sọ̀rọ̀, eṣú sì dé,

àti kòkòrò ní àìníye,

35 wọn sì jẹ gbogbo ewé ilẹ̀ wọn,

wọ́n sì jẹ èso ilẹ̀ wọn run.

36 Nígbà náà, ó kọlu gbogbo àwọn ilẹ̀ wọn,

ààyò gbogbo ipá wọn.

37 Ó mú Israẹli jáde

ti òun ti fàdákà àti wúrà,

nínú ẹ̀yà rẹ̀ kò sí aláìlera kan.

38 Inú Ejibiti dùn nígbà tí wọn ń lọ,

nítorí ẹ̀rù àwọn Israẹli ń bá wọ́n.

39 Ó ta àwọsánmọ̀ fún ìbòrí,

àti iná láti fún wọn ní ìmọ́lẹ̀ lálẹ́.

40 Wọn béèrè, ó sì mú ẹyẹ àparò wá,

ó sì fi oúnjẹ ọ̀run tẹ́ wọn lọ́rùn.

41 Ó sì la àpáta, ó sì mú omi jáde;

gẹ́gẹ́ bí odò tí ń sàn níbi gbígbẹ.

42 Nítorí ó rántí ìlérí mímọ́ rẹ̀

àti Abrahamu ìránṣẹ́ rẹ̀.

43 Ó sì fi ayọ̀ mú àwọn ènìyàn rẹ̀ jáde

pẹ̀lú ayọ̀ ní ó yan àyànfẹ́ rẹ̀

44 Ó fún wọn ní ilẹ̀ ìní náà,

wọ́n sì jogún iṣẹ́ àwọn ènìyàn náà,

45 kí wọn kí ó lè máa pa àṣẹ rẹ̀ mọ́

kí wọn kí ó lè kíyèsi òfin rẹ̀.

Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.

Veja também

Publicidade
Bíblia Online Bíblia Online

Bíblia Online • Versão: 2026-06-15_21-32-39-