Publicidade

Salmos 86

Àdúrà ti Dafidi.

1 Gbọ́, Olúwa, kí o sì dá mi lóhùn,

nítorí mo jẹ́ tálákà àti aláìní.

2 Dáàbò bò ayé mi, nítorí a ti yà mí sọ́tọ̀ fún ọ:

ìwọ ni Ọlọ́run mi,

gbà ìránṣẹ́ rẹ là

tí ó gbẹ́kẹ̀lé ọ.

3 Ṣàánú fún mi, Olúwa,

nítorí èmi ń pè ọ́ ní gbogbo ọjọ́.

4 Mú ayọ̀ wà fún ìránṣẹ́ rẹ,

nítorí ìwọ, Olúwa,

ni mo gbé ọkàn mí sókè sí.

5 Ìwọ ń dáríjì, ìwọ sì dára, Olúwa,

ìwọ sì ṣàánú fún gbogbo àwọn tí ń ké pè ọ́.

6 Gbọ́ àdúrà mi, Olúwa;

tẹ́tí sí ẹkún mi fún àánú.

7 Ní ọjọ́ ìpọ́njú mi èmi yóò pè ọ́,

nítorí ìwọ yóò dá mi lóhùn.

8 Nínú àwọn òrìṣà kò sí ẹni tí ó dàbí i rẹ, Olúwa:

kò sí àwọn iṣẹ́ tí a lè fiwé tìrẹ.

9 Gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè tí ìwọ dá

yóò wá láti wá jọ́sìn níwájú rẹ, Olúwa;

wọn ó mú ògo wà fún orúkọ rẹ̀.

10 Nítorí pé ìwọ tóbi, ìwọ sì ń ṣe ohun ìyanu;

ìwọ nìkan ni Ọlọ́run.

11 Kọ́ mi ní ọ̀nà rẹ, Olúwa,

èmi ó sì máa rìn nínú òtítọ́ rẹ;

fún mi ní ọkàn tí kì í yapa,

kí èmi kí ó ba lè bẹ̀rù orúkọ rẹ.

12 Èmi ó yìn ọ́, Olúwa Ọlọ́run mi, pẹ̀lú gbogbo ọkàn mi;

èmi ó fògo fún orúkọ rẹ títí láé.

13 Nítorí títóbi ni ìfẹ́ rẹ si mi;

ìwọ ti gbà mí kúrò nínú ọ̀gbun isà òkú.

14 Àwọn onígbèéraga ń dojúkọ mí, Ọlọ́run;

àti ìjọ àwọn alágbára ń wá

ọkàn mi kiri,

wọn kò sì fi ọ́ pè.

15 Ṣùgbọ́n ìwọ, Olúwa, jẹ́ aláàánú àti Ọlọ́run olójúrere,

Ó lọ́ra láti bínú, Ó sì pọ̀ ní ìfẹ́ àti òtítọ́.

16 Yípadà sí mi kí o sì ṣàánú fún mi;

fún àwọn ènìyàn rẹ ní agbára

kí o sì gba ọ̀dọ́mọkùnrin ìránṣẹ́bìnrin rẹ là.

17 Fi àmì hàn mí fún rere,

kí àwọn tí ó kórìíra mi lè ri,

kí ojú lè tì wọ́n, nítorí ìwọ Olúwa

ni ó ti tù mí nínú.

Veja também

Publicidade
Bíblia Online Bíblia Online

Bíblia Online • Versão: 2026-06-15_21-32-39-