Publicidade

Salmos 30

Saamu. Orin. Fún ìyàsímímọ́ Tẹmpili. Ti Dafidi.

1 Èmi yóò kókìkí i rẹ, Olúwa,

nítorí ìwọ ni ó gbé mi lékè

tí ìwọ kò sì jẹ́ kí àwọn ọ̀tá mi kí ó yọ̀ mí.

2 Olúwa Ọlọ́run mi, èmi ké pè ọ́ fún ìrànlọ́wọ́,

ìwọ sì ti wò mí sàn.

3 Olúwa, ìwọ ti yọ ọkàn mi jáde kúrò nínú isà òkú,

mú mi padà bọ̀ sípò alààyè kí èmi má ba à lọ sínú ihò.

4 Kọ orin ìyìn sí Olúwa, ẹ̀yin olódodo;

kí ẹ sì fi ọpẹ́ fún orúkọ rẹ̀ mímọ́.

5 Nítorí pé ìbínú rẹ̀ wà fún ìgbà díẹ̀,

ojúrere rẹ̀ wà títí ayérayé;

ẹkún lè pẹ́ títí di alẹ́,

ṣùgbọ́n ayọ̀ yóò wá ní òwúrọ̀.

6 Ní ìgbà ayé mi, mo wí pé,

"a kì yóò ṣí mi ní ipò padà."

7 Nípa ojúrere rẹ, Olúwa,

ìwọ ti gbé mi kalẹ̀ bí òkè tí ó ní agbára;

ìwọ pa ojú rẹ mọ́,

àyà sì fò mí.

8 Sí ọ Olúwa, ni mo ké pè é;

àti sí Olúwa ni mo sọkún fún àánú:

9 "Èrè kí ni ó wà nínú ikú ìparun mi,

nínú lílọ sí ihò mi?

Eruku yóò a yìn ọ́ bí?

Ǹjẹ́ yóò sọ nípa òdodo rẹ?

10 Gbọ́, Olúwa, kí o sì ṣàánú fún mi;

ìwọ Olúwa, jẹ́ olùrànlọ́wọ́ mi."

11 Ìwọ ti yí ìkáàánú mi di ijó fún mi;

ìwọ sì ti bọ́ aṣọ ọ̀fọ̀ mi, o sì fi aṣọ ayọ̀ wọ̀ mí,

12 nítorí ìdí èyí ni kí ọkàn mi máa yìn ọ́, kí o má sì ṣe dákẹ́.

Ìwọ Olúwa Ọlọ́run mi, èmi yóò máa fi ọpẹ́ fún ọ títí láé.

Veja também

Publicidade
Bíblia Online Bíblia Online

Bíblia Online • Versão: 2026-06-16_06-50-08-