Publicidade

Salmos 146

1 Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.

Fi ìyìn fún Olúwa, ìwọ ọkàn mi.

2 Èmi yóò yin Olúwa ní gbogbo ayé mi,

èmi yóò kọrin ìyìn sí Ọlọ́run, níwọ̀n ìgbà tí mo bá wà láààyè.

3 Ẹ má ṣe ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú àwọn ọmọ-aládé,

àní, ọmọ ènìyàn,

lọ́wọ́ ẹni tí kò sí ìrànlọ́wọ́.

4 Ẹ̀mí rẹ jáde lọ, ó padà sí erùpẹ̀,

ní ọjọ́ náà gan, èrò wọn yóò di òfo.

5 Ìbùkún ni fún ẹni tí

Ọlọ́run Jakọbu ń ṣe ìrànlọ́wọ́ rẹ̀

tí ìrètí rẹ̀ wà nínú Olúwa Ọlọ́run rẹ̀.

6 Ẹni tí ó dá ọ̀run àti ayé,

òkun àti ohun gbogbo tí ń bẹ nínú wọn,

ẹni tí ó pa òtítọ́ mọ́ títí ayé.

7 Ẹni tí ń ṣe ìdájọ́ àwọn tí a ni lára,

tí ó fi oúnjẹ fún àwọn tí ebi ń pa,

Olúwa, tú àwọn oǹdè sílẹ̀,

8 Olúwa mú àwọn afọ́jú ríran,

Olúwa, gbé àwọn tí a rẹ̀ sílẹ̀ ga,

Olúwa fẹ́ràn àwọn olódodo.

9 Olúwa ń dá ààbò bo àwọn àlejò

ó sì ń dá àwọn aláìní baba àti opó sí

ṣùgbọ́n ó ba ọ̀nà àwọn ènìyàn búburú jẹ́.

10 Olúwa jẹ ọba títí láé;

Ọlọ́run rẹ, ìwọ Sioni, àti fún gbogbo ìran.

Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.

Veja também

Publicidade
Bíblia Online Bíblia Online

Bíblia Online • Versão: 2026-06-15_21-32-39-