Publicidade

Salmos 97

1 Olúwa jẹ ọba, jẹ́ kí ayé kí ó yọ̀

jẹ́ kí inú ọ̀pọ̀lọpọ̀ erékùṣù kí ó dùn.

2 Ojú ọ̀run àti òkùnkùn yíká

òdodo àti ìdájọ́ ni ó ṣe ìpilẹ̀ṣẹ̀ ìtẹ́ rẹ̀.

3 Iná ń jó níwájú rẹ̀. Ó sì ń jó àwọn ọ̀tá rẹ̀ yíkákiri.

4 Ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ tàn ó sì kárí ayé

ayé rí i ó sì wárìrì.

5 Òkè gíga yọ́ gẹ́gẹ́ bí ìda níwájú Olúwa,

níwájú Olúwa gbogbo ayé.

6 Àwọn ọ̀run ròyìn òdodo rẹ̀, gbogbo ènìyàn sì rí ògo rẹ̀.

7 Gbogbo àwọn tí ń sin ère fínfín ni ojú yóò tì,

àwọn tí ń fi ère gbéraga,

ẹ máa sìn ín, gbogbo ẹ̀yin ọlọ́run!

8 Sioni gbọ́, inú rẹ̀ sì dùn

inú àwọn ilé Juda sì dùn,

nítorí ìdájọ́ rẹ, Olúwa.

9 Nítorí pé ìwọ, Olúwa, ni ó ga ju gbogbo ayé lọ

ìwọ ni ó ga ju gbogbo òrìṣà lọ.

10 Jẹ kí gbogbo àwọn tí ó fẹ́

Olúwa, kórìíra ibi, ó pa ọkàn àwọn ènìyàn mímọ́ rẹ̀ mọ́

ó gbà wọ́n ní ọwọ́ àwọn ènìyàn búburú.

11 Ìmọ́lẹ̀ tàn sórí àwọn olódodo

àti ayọ̀ nínú àlàyé ọkàn.

12 Ẹ yọ̀ nínú Olúwa, ẹ̀yin tí ẹ jẹ́ olódodo,

kí ẹ sì yin orúkọ rẹ̀ mímọ́.

Veja também

Publicidade
Bíblia Online Bíblia Online

Bíblia Online • Versão: 2026-06-15_21-32-39-