Publicidade

Salmos 136

1 Ẹ fi ọpẹ́ fún Olúwa nítorí tí ó ṣeun;

nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.

2 Ẹ fi ọpẹ́ fún Ọlọ́run àwọn ọlọ́run:

nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.

3 Ẹ fi ọpẹ́ fún Olúwa àwọn olúwa,

nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.

4 Fún Òun nìkan tí ń ṣiṣẹ́ ìyanu ńlá;

nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.

5 Fún ẹni tí ó fi ọgbọ́n dá ọ̀run;

nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.

6 Fún ẹni tí ó tẹ́ ilẹ̀ lórí omi;

nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.

7 Fún ẹni tí ó dá àwọn ìmọ́lẹ̀ ńlá;

nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.

8 Òòrùn láti jẹ ọba ọ̀sán;

nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.

9 Òṣùpá àti ìràwọ̀ láti jẹ ọba òru;

nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.

10 Fún ẹni tí ó kọlu Ejibiti lára àwọn àkọ́bí wọn;

nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.

11 Ó sì mú Israẹli jáde kúrò láàrín wọn;

nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.

12 Pẹ̀lú ọwọ́ agbára àti apá nínà;

nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.

13 Fún ẹni tí ó pín Òkun pupa ní ìyà;

nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.

14 Ó sì mú Israẹli kọjá láàrín rẹ̀

nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.

15 Ṣùgbọ́n ó bi Farao àti ogun rẹ̀ ṣubú nínú Òkun pupa;

nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.

16 Fún ẹni tí ó sin àwọn ènìyàn rẹ̀ la aginjù já

nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.

17 Fún ẹni tí ó kọlu àwọn ọba ńlá;

nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.

18 Ó sì pa àwọn ọba olókìkí

nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.

19 Sihoni, ọba àwọn ará Amori

nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.

20 Àti Ogu, ọba Baṣani;

nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.

21 Ó sì fi ilẹ̀ wọn fún ni ní ìní,

nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.

22 Ìní fún Israẹli, ìránṣẹ́ rẹ̀,

nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.

23 Ẹni tí ó rántí wa ní ìwà ìrẹ̀lẹ̀ wa;

nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.

24 Ó sì dá wa ní ìdè lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wa;

nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.

25 Ẹni tí ó fi oúnjẹ fún àwọn ẹ̀dá gbogbo

nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.

26 Ẹ fi ọpẹ́ fún Ọlọ́run ọ̀run;

nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.

Veja também

Publicidade
Bíblia Online Bíblia Online

Bíblia Online • Versão: 2026-06-16_06-50-08-