Publicidade

Salmos 16

Miktamu ti Dafidi.

1 Pa mí mọ́, Ọlọ́run,

nítorí nínú rẹ ni ààbò mi wà.

2 Mo sọ fún Olúwa, "Ìwọ ni Olúwa mi,

lẹ́yìn rẹ èmi kò ní ìre kan."

3 Sí àwọn ènìyàn tí ó wà ní ayé,

àwọn ni ológo nínú èyí tí ayọ̀ mí wà.

4 Ìṣòro àwọn wọ̀n-ọn-nì yóò pọ̀ sí i, àní àwọn tí ń tọ ọlọ́run mìíràn lẹ́yìn.

Ẹbọ ohun mímu ẹ̀jẹ̀ wọn ni èmi kì yóò ta sílẹ̀,

bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò dá orúkọ wọn lẹ́nu mi.

5 Olúwa, ni ìpín ìní mi tí mo yàn àti ago mi,

ó ti pa ohun tí í ṣe tèmi mọ́.

6 Okùn ààlà ilẹ̀ ti bọ́ sí ọ̀dọ̀ mi ní ibi dídára;

nítòótọ́ mo ti ní ogún rere.

7 Èmi yóò yin Olúwa, ẹni tí ó gbà mí ní ìyànjú;

ní òru, ọkàn mí ń bá mi sọ̀rọ̀.

8 Mo ti gbé Olúwa síwájú mi ní ìgbà gbogbo.

Nítorí tí ó wà ní ọwọ́ ọ̀tún mi, a kì yóò mì mí.

9 Nítorí èyí, ọkàn mi yọ̀, ahọ́n mi pẹ̀lú ń fò fáyọ̀;

ara mi pẹ̀lú yóò sinmi ní ààbò,

10 nítorí ìwọ kò ní fi ọ̀kan sílẹ̀ nínú isà òkú,

tàbí kí ìwọ jẹ́ kí ẹni mímọ́ rẹ kí ó rí ìdíbàjẹ́.

11 Ìwọ ti fi ipa ọ̀nà ìyè hàn mí;

Ìwọ yóò kún mi pẹ̀lú ayọ̀ ní iwájú rẹ,

pẹ̀lú ìdùnnú ayérayé ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ.

Veja também

Publicidade
Bíblia Online Bíblia Online

Bíblia Online • Versão: 2026-06-15_21-32-39-