Publicidade

Salmos 128

Orin fún ìgòkè.

1 Ìbùkún ni fún gbogbo ẹni tí ó bẹ̀rù Olúwa:

tí ó sì ń rìn ní ọ̀nà rẹ̀.

2 Nítorí tí ìwọ yóò jẹ iṣẹ́ ọwọ́ rẹ

ìbùkún ni fún ọ; yóò sì dára fún ọ.

3 Obìnrin rẹ yóò dàbí àjàrà rere

eléso púpọ̀ ní àárín ilé rẹ;

àwọn ọmọ rẹ yóò dàbí igi olifi tí ó yí tábìlì rẹ ká.

4 Kíyèsi i pé, bẹ́ẹ̀ ni a ó bùsi i fún ọkùnrin náà,

tí ó bẹ̀rù Olúwa.

5 Olúwa kí ó bùsi i fún ọ láti Sioni wá,

kí ìwọ kí ó sì máa rí ìre

Jerusalẹmu ní ọjọ́ ayé rẹ gbogbo.

6 Bẹ́ẹ̀ ni kí ìwọ kí ó sì máa rí àti ọmọdọ́mọ rẹ.

Láti àlàáfíà lára Israẹli.

Veja também

Publicidade
Bíblia Online Bíblia Online

Bíblia Online • Versão: 2026-06-15_21-32-39-