Publicidade

Salmos 80

Fún adarí orin. Tí ohùn "Lílì Ti Májẹ̀mú." Ti Safu. Saamu.

1 Gbọ́ tiwa, ìwọ olùṣọ́-àgùntàn Israẹli;

ìwọ tí ó darí Josẹfu bí ọ̀wọ́ ẹran.

Ìwọ tí o jókòó lórí ìtẹ́ láàrín Kérúbù,

tàn jáde 2 níwájú Efraimu, Benjamini àti Manase.

Ru agbára rẹ̀ sókè;

wá fún ìgbàlà wa.

3 Mú wa padà bọ̀ sípò, ìwọ Ọlọ́run;

jẹ́ kí ojú rẹ kí ó tan ìmọ́lẹ̀ sí wa,

kí a bá à lè gbà wá là.

4 Olúwa Ọlọ́run alágbára,

ìbínú rẹ̀ yóò ti pẹ́ tó

sí àdúrà àwọn ènìyàn rẹ?

5 Ìwọ ti fi oúnjẹ bọ́ wọn

ìwọ ti mú wọn wa ẹkún mu ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́.

6 Ìwọ sọ wá di ẹlẹ́yà fún àwọn aládùúgbò wa,

àwọn ọ̀tá wa sì ń yọ̀ wá.

7 Tún wa yípadà, ìwọ, Ọlọ́run alágbára;

jẹ́ kí ojú rẹ tàn sí wa,

kí a ba à lè gbà wá là.

8 Ìwọ mú àjàrà jáde láti Ejibiti;

ìwọ lé àwọn kèfèrí jáde, o sì gbìn ín.

9 Ìwọ ṣí ààyè sílẹ̀ fún un,

ìwọ sì mu ta gbòǹgbò jinlẹ̀

ó sì kún ilẹ̀ náà.

10 A bò àwọn òkè mọ́lẹ̀ òkè pẹ̀lú òjìji rẹ̀,

ẹ̀ka rẹ̀ dàbí kedari Ọlọ́run.

11 O yọ ẹ̀ka rẹ̀ sínú Òkun,

ọwọ́ rẹ̀ sí odò ńlá nì.

12 Èéṣe tí ìwọ fi wó odi rẹ̀

tí àwọn ènìyàn tí ó ń kọjá fi ń ṣa èso rẹ̀?

13 Ìmàdò láti inú igbó ń bá a jẹ́

àti ẹranko igbó ń jẹ ẹ́ run.

14 Yípadà sí wa, àwa ń bẹ̀ ọ́, Ọlọ́run alágbára!

Bojú wolẹ̀ láti ọ̀run kí o sì wò ó!

Kí o sì bẹ àjàrà yìí wò,

15 gbòǹgbò èyí tí ọwọ́ ọ̀tún rẹ ti gbìn,

àti ẹ̀ka tí ìwọ ti mú lágbára fún ara rẹ.

16 A gé àjàrà rẹ lulẹ̀, a ti fi iná sun ún;

ní ìfibú, àwọn ènìyàn rẹ̀ ń ṣègbé.

17 Jẹ́ kí ọwọ́ rẹ kí ó wà lára ọkùnrin tí ó wà ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ,

ọmọ ènìyàn tí ìwọ tí gbé kalẹ̀ fún ara rẹ.

18 Nígbà náà àwa kí yóò yípadà kúrò lọ́dọ̀ rẹ;

mú wa yè, àwa o sì máa pe orúkọ rẹ.

19 Tún wa yípadà, Olúwa Ọlọ́run alágbára;

kí ojú rẹ̀ kí ó tan ìmọ́lẹ̀ sí wa,

kí á ba à lè gbà wá là.

Veja também

Publicidade
Bíblia Online Bíblia Online

Bíblia Online • Versão: 2026-06-15_21-32-39-