1 Àwọn ọ̀run ń sọ nípa ti ògo Ọlọ́run;
àwọsánmọ̀ ń sọ nípa ti iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀.
2 Wọ́n ń fọhùn ní ọjọ́ dé ọjọ́;
wọ́n ń fi ìmọ̀ hàn ní alẹ́ dé alẹ́.
3 Kò sí ohùn tàbí èdè
níbi tí a kò gbé gbọ́ ìró wọn.
4 19.4: Ro 10.18. Ohùn wọn jáde lọ sí gbogbo orílẹ̀ ayé,
ọ̀rọ̀ wọn títí dé òpin ilẹ̀ ayé.
Ó ti kọ́ àgọ́ fún oòrùn nínú àwọn ọ̀run.
5 Tí ó dàbí ọkọ ìyàwó tí ó ń jáde ti yàrá rẹ̀ wá,
òun yọ bí alágbára ọkùnrin tí ó ń sáré ìje.
6 Ìjáde lọ rẹ̀ ni láti òpin ọ̀run wá
àti àyíká rẹ̀ sì dé ìpínlẹ̀ rẹ̀;
kò sì sí ohun tí ó pamọ́ kúrò nínú oore rẹ̀.
7 Pípé ni òfin Olúwa,
ó ń yí ọkàn padà.
Ẹ̀rí Olúwa dánilójú,
ó sọ òpè di ọlọ́gbọ́n.
8 Ìlànà Olúwa tọ̀nà,
ó ń fi ayọ̀ fún ọkàn.
Àṣẹ Olúwa ni mímọ́,
ó ń fi ìmọ́lẹ̀ fún ojú.